Skip to main content

AKÍNWÙMÍ ÌṢỌ̀LÁ (Ẹ wá w’ẹwà èdè l’ẹ́nu Àwòko) By Níyì Ọ̀ṣúndáre

March 24, 2018

AKÍNWÙMÍ ÌṢỌ̀LÁ
(Ẹ wá w’ẹwà èdè l’ẹ́nu Àwòko)
Ẹní bá m’agbe, kó bá wa dárò aró
Ẹní bá m’àlùkò, kó bá wa dárò osùn
Ẹní mọ lékelèké, kó bá wa dárò ẹfun
Gbogbo ẹ̀yin tó m’Akínwùmí Ìṣọ̀lá
Ẹ mà wá dárò ẹni ire tó lọ.


Akínwùmí, ọmọ Ìṣọ̀lá
Àwòko tó f’èdè ìjìnlẹ̀ kọ́lé ọgbọ́n
Tó wá fi làákàyè ṣe òrùlé rẹ̀
Oyin to to to l’ọ̀rọ̀ l’ẹ́nuu rẹ̀
Àgbáyunun l’ọgbọ́n tó b’áhán-an rẹ̀ ṣè’mùlẹ̀
Ọgbọ́n wọ’nú ọgbọ́n
Ìmọ̀ràn w’ọnú àgbékà
Làákàyè di baba ìsàlẹ̀ l’áwùjọ apínrọ̀
Akínwùmí fì’mọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣẹ̀ṣọ́
Ó fi dídùn ohùn ṣ’ayé l’óore

Ẹní bá m’agbe, kó bá wa dárò aró

Tiwa n tiwa
Tàkísà n tààtàn
Ìyà jẹ’gún títí, igún pá lórí
Ìyà j’ọ̀pọ̀lọ́, ọ̀pọ̀lọ́ gbàgbé ìrù
Ìyà j’Adúláwọ̀,
Wọ́n gbé iyì ìṣẹ̀dálẹ̀ sọnù
Wọ́n kọ̀yìn sí ọgbọ́n abínibí
Wọ́n t’àpá sí ọgbọ́n àdáyébá
Wọ́n ṣe ṣíọ̀ sí àwọn nǹkan àdáyémọ̀
Akínwùmí kígbe lóhùn rara; ó ní
“Kére o, ẹ tẹ́tí ẹ gbọ́, ẹ̀yin akótilétà,
Abọ̀rìṣà òní, bíi pé kò sí tàná;
Odò tó bá gbàgbé orísun rẹ̀, gbígbẹ ní ń gbẹ
Àwọn ènìyàn tó bá gúnyán ara wọn kéré
Wọ́n ti fi gọ̀ǹgọ̀ fa ebi àparìn

Ẹní bá m’agbe, kó bá wa dárò aró

Òkàwé
Ọ̀kọ̀wé
Ọ̀mọ̀wé
Ọ̀jọ̀gbọ́n àtàtà tó finú jínjìn ṣ’ẹwà ìmọ̀
Tani ò mọ̀ pé
Olóye l’ọ̀rọ̀ bá wí

Tani ò mọ̀ pé ọ̀mọ̀ràn ló ṣ’òwò àgbékà
Akínwùmí ló m’ojú ọ̀rọ̀ àdììtú:

Ṣaworo, Ṣàwòrò, Ṣaworo Idẹ
Ẹ wá w’adé tó di iná ajere lóríi Jàǹdùkú Òṣèlú
Kòkòrò ajẹ̀lúrun, apàlúlẹ́kún jayé.
Ẹ wo Kòṣeégbé kí ẹ mọyìi pàkúté ọ̀tẹ̀
Ní’lùú tí ìwà ìbàjẹ́ ti jẹ gómìnà
T’áwọn wọ̀ǹbìà ti gbìmọ̀
Láti sọ’lé Atúnlùúṣe dahoro
Ẹ bá mi kí Campus Queen kú àbọ̀,
Olójú edé, oníbàdí òréke
Háà! Gbágà!! Ọ̀rọ̀ ò wọ̀
L’ọ́jọ́ tí Madam Tinúbú pàdé Ẹfúnṣetán Aníwúrà
Orí ìtàgé mì jìjì, gbogbo ìlú pa rọ́rọ́
Bẹ́ẹ̀ náà la mọ̀, pé ogún ọmọdé kò le ṣeré f’ógún ọdún. . . .
Háà! Akínwùmí Ìṣọ̀lá,

Mélòó la ó kà léyín Adépèléè rẹ . . . ….?

Ẹní bá m’agbe, kó bá wa dárò aró

Òtokítokí, Agbédègbẹyọ̀
O fí Faransé ṣeré alẹ́
O fi Gẹ̀ẹ́sì dọ́wẹ̀ẹ́kẹ̀ àárọ̀
Bẹ́ẹ̀ ni, Yorùbá gbajú gbayì
L’ẹ́nu Akínwùmí, Àǹjọ̀nnú-èdè
Ká sọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀, ká k’éwì bí ẹní k’Ifá
Ká kán oyin èdè s’étíi mùtúmùwà

Ẹní bá m’agbe, kó bá wa dárò aró

Sùnun’re o, ẹni ayé yẹ, tí ọ̀run dùn fún
Bá wa kí Fágúnwà, Ọmọ Akọ̀wédìran
Àti Fálétí, Onígègé-àrà.
Ẹni rere kú
Ẹni rere kù

Akínwùmí ọmọ Ìṣọ̀lá, ìwọ ni mò ń kéé sí.


Ẹní bá m’agbe, kó bá wa dárò aró
Ẹní bá m’àlùkò, kó bá wa dárò osùn
Ẹní mọ lékelèké, kó bá wa dárò ẹfun
Gbogbo ẹ̀yin tó m’Akínwùmí Ìṣọ̀lá
Ẹ mà wá dárò ẹni ire tó lọ.

Níyì Ọ̀ṣúndáre

Image

Topics
POETRY